Isaiah 34:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí. Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀, yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀. Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ, olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Owiwi yio tẹ́ itẹ́ rẹ̀ sibẹ̀, yio yé, yio si pa, yio si kojọ labẹ ojiji rẹ̀: awọn gúnugú yio pejọ sibẹ pẹlu, olukuluku pẹlu ẹnikeji rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀, yóò yé, yóò sì pa, yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀: àwọn gúnnugún yóò péjọ ṣibẹ̀ pẹ̀lú, olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.