Isaiah 34:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè, inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀. Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ibinu Oluwa mbẹ lara gbogbo orilẹ-ède, ati irúnu rẹ̀ lori gbogbo ogun wọn: o ti pa wọn run patapata, o ti fi wọn fun pipa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ibínú OLÚWA ń bẹ lára gbogbo orílẹ̀-èdè, àti irunú un rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn: o ti fi wọ́n fún pipa,