Isaiah 34:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànù a óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé. Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà, àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ogun ọrun ni yio di yiyọ́, a o si ká awọn ọrun jọ bi takàda, gbogbo ogun wọn yio si ṣubu lulẹ, bi ewe ti ibọ́ kuro lara àjara, ati bi bibọ́ eso lara igi ọ̀pọtọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́, a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i takàdá, gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀, bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà, àti bí i bíbọ́ èṣo lára igi ọ̀pọ̀tọ́.