Isaiah 34:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá. Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀, ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn agbanrere yio bá wọn sọkalẹ wá, ati awọn ẹgbọ̀rọ malu pẹlu awọn akọ malu; ilẹ wọn li a o fi ẹ̀jẹ rin, a o si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ra.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn àgbáǹréré yóò ba wọn ṣọ̀kalẹ̀ wá, àti àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù pẹ̀lú àwọn akọ màlúù, ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin, a ó si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di Ọlọ́ràá.