Isaiah 35:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada, wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin, ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn. Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbà ìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.