Isaiah 35:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀, a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́; nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá, àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti opópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà-Mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.