Isaiah 36:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Eliakimu ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, èdè Aramaiki ni kí o fi bá wa sọ̀rọ̀, nítorí pé àwa náà gbọ́ Aramaiki. Má fi èdè Juda bá wa sọ̀rọ̀ kí àwọn ará wa tí ó wà lórí odi má baà gbọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni Eliákímù, Ṣébínà àti Jóà sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”