Isaiah 36:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Rabuṣake dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati oluwa yín nìkan ni oluwa mi rán mi pé kí n jíṣẹ́ yìí fún ni? Ṣé kò yẹ kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jókòó lórí odi ìlú yìí fetí wọn gbọ́ pé, ati àwọn ati ẹ̀yin, ẹ ti gbé, ẹ o máa jẹ ìgbọ̀nsẹ̀ ara yín, ẹ óo sì máa mu ìtọ̀ yín?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò wí pé ọ̀gá yín àti ẹ̀yin nìkan ni ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ni, tí kì í sì ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó jókòó lórí ògiri, àwọn tí ó jẹ́ pé wọn yóò jẹ ìgbẹ́ wọn tí wọ́n yóò sì mu ìtọ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà?”