Isaiah 36:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ Hesekaya; nítorí ọba Asiria ní kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia kí ẹ jáde tọ òun wá. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, olukuluku yín ni yóo máa jẹ èso àjàrà ati èso ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, olukuluku yín yóo sì máa mu omi ninu kànga rẹ̀;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ máṣe fetisi ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Ẹ fi ẹ̀bun bá mi rẹ́, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá: ki olukuluku nyin ma jẹ ninu àjara rẹ̀, ati olukuluku nyin ninu igi ọ̀pọtọ́ rẹ̀, ki olukuluku nyin si ma mu omi ninu àmu on tikalarẹ̀;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Heṣekáyà. Ohun tí ọba Áṣíríà wí nìyìí: Ẹ ṣètò àlàáfíà pẹ̀lúù mi kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mumi nínú kàǹga rẹ̀,