Isaiah 36:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ ṣọ́ra kí Hesekaya má baà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì yín lọ́nà, kí ó máa sọ pé, ‘OLUWA yóo gbà wá.’ Ṣé ọ̀kankan ninu àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ti gba ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ọba Asiria rí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ ṣọra ki Hesekiah ki o má pa nyin niyè dà wipe, Oluwa yio gbà wa, ọkan ninu òriṣa awọn orilẹ-ède ha gba ilẹ rẹ̀ lọwọ ọba Assiria ri bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà sì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘OLÚWA yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀ èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà bí?