Isaiah 36:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa, ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin wá sọ́dọ̀ Hesekaya pẹlu àwọn ti aṣọ wọn tí wọ́n ti fàya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì sọ ohun tí Rabuṣake wí fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Eliakimu, ọmọ Hilkia, ti iṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa, ọmọ Asafu akọwe iranti, wá sọdọ Hesekiah ti awọn ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni Eliákímù ọmọ Híkílíà alákóṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.