Isaiah 36:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Báwo ni ó ṣe lè lé ẹni tí ó kéré jù ninu àwọn olórí-ogun oluwa mi pada sẹ́yìn, nígbà tí ó jẹ́ pé Ijipti ni ó gbójú lé pé wọn óo fún un ní kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ iwọ o ti ṣe le yi oju balogun kan pada ninu awọn ti o rẹhin jù ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si ngbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́, ati fun ẹlẹṣin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kanṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn ìjòyè ọ̀gá mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin?