Isaiah 37:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si ilẹ gbogbo bi nwọn ti pa wọn run patapata: a o si gbà iwọ bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Ásíríà ti ṣe sí àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó pa wọ́n run pátapáta. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?