Isaiah 37:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun bi? bi Gosani, ati Harani ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti nwọn ti wà ni Telassari?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gósénì, Háránì, Résípì àti àwọn ènìyàn Ẹ́dẹ́nì tí wọ́n wà ní ìlú Áṣárì?