Isaiah 37:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà, o ní, ‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ, mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni. Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀, ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀. Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀, ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipasẹ awọn iranṣẹ rẹ li o ti kẹgàn Oluwa, ti o si ti wipe, Ni ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ mi, emi ti goke wá si oke awọn oke giga, si ẹba Lebanoni; emi o si ke igi kedari rẹ̀ giga lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀, emi o si wá si ẹnu agbègbe rẹ̀, ati si igbó Karmeli rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa àwọn oníṣẹ́ rẹ ìwọ ti mú àbùkù bá OLÚWA. Ìwọ sì ti sọ wí pé ‘pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin mi Èmi ti gun orí òkè ńlá ńlá, ibi gíga jùlọ ti Lébánónì. Èmi ti gé igi kédárì rẹ tí ó ga jùlọ lulẹ̀, àti àyànfẹ́ igi páínì. Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ, igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.