Isaiah 37:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọn má ní agbára mọ́, kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà. Kí wọ́n dàbí ewé inú oko ati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù bí koríko tí ó hù lórí òrùlé, tíí gbẹ kí ó tó dàgbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni awọn olugbé wọn fi ṣe alainipa, aiya fò wọn, nwọn si dãmu: nwọn dabi koriko igbẹ, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko lori okè ilé, ati bi ọkà ti igbẹ ki o to dàgba soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù, ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì. Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhù tuntun, gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé, tí ó jóná kí ó tó dàgbà ṣókè.