Isaiah 37:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni o si jẹ àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun yi; ati li ọdun keji eyiti o sọ jade ninu ọkanna: ati li ọdun kẹta ẹ fọnrugbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba àjara, ki ẹ si jẹ eso wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ Ìwọ Heṣekáyà: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnraà rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara ìyẹn. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èṣo wọn.