Isaiah 37:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, ohun tí OLUWA wí nípa ọba Asiria ni pé, ‘Kò ní wọ inú ìlú yìí, kò sì ní ta ọfà sí i. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò ní kó apata wọ inú rẹ̀. Wọn kò sì ní dó tì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi ni Oluwa wi niti ọba Assiria, on kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio si mu asà wá siwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio wà odi tì i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA wí nípa ọba Ásíríà: “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájúu rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.