Isaiah 37:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Angẹli OLUWA bá lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn (185,000) ninu wọn. Nígbà tí wọn jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ òkú kún ilẹ̀ lọ kítikìti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Angeli Oluwa si jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan o le ẹgbẹ̃dọgbọn ni budo awọn ara Assiria; nigbati nwọn si dide lowurọ kùtukutu, kiyesi i, gbogbo wọn jẹ okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà ni ańgẹ́lì OLÚWA jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Ásíríà. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!