Isaiah 37:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, ó lọ bọ Nisiroku, oriṣa rẹ̀, àwọn meji ninu àwọn ọmọ rẹ̀: Adirameleki ati Ṣareseri, sì fi idà gún un pa, wọ́n bá sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si di igbati o ṣe, bi o ti ntẹriba ni ile Nisroki oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣaresari awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a; nwọn si salà si ilẹ Armenia: Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹ́ḿpìlì Níṣírókì òrìṣà rẹ, àwọn ọmọ rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣáréṣà gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹsahadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.