Isaiah 37:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ṣeéṣe kí OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbọ́ iṣẹ́ tí ọba Asiria rán Rabuṣake, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó wá fi Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà, kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Nítorí náà gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè kí o gbadura fún àwọn eniyan tí ó kù.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ ọ̀rọ Rabṣake, ẹniti oluwa rẹ̀ ọba Assiria ti rán lati gàn Ọlọrun alãyè, yio si ba ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́ wi: nitorina gbe adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó lè jẹ́ pé OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Ásíríà ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láàyè.”