Isaiah 37:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gbọ́ a nwi niti Tirhaka ọba Etiopia, pe, O mbọ̀ wá ba iwọ jagun. Nigbati o si gbọ́, o rán awọn ikọ̀ lọ sọdọ Hesekiah, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò yìí Ṣenakérúbù gbọ́ ìròyìn kan pé Tíhákà ará Kúṣì ọba Éjíbítì ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Heṣekáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: