Isaiah 38:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI ọjọ wọnni Hesekiah ṣaisàn de oju ikú. Woli Isaiah ọmọ Amosi si wá sọdọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Bayi ni Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́: nitori iwọ o kú, o ki yio si yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà ni Heṣekáyà ṣe àìṣàn dé ojú ikú. Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: palẹ̀ iléẹ̀ rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìṣàn yìí.”