Isaiah 39:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò náà Merodaki Baladani ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn rán àwọn ikọ̀ kan sí Hesekaya, nítorí ó gbọ́ pé ara rẹ̀ kò ti dá tẹ́lẹ̀ ṣugbọn ara rẹ̀ ti wá le.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI akoko na ni Merodaki-baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, rán iwe ati ọrẹ si Hesekiah: nitori o ti gbọ́ pe o ti ṣaisàn, o si ti sàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà ni Méródákì-Báládánì ọmọ Báládánì ọba Bábílónì fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Heṣekáyà, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn.