Isaiah 39:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya gbà wọ́n lálejò, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fadaka ati wúrà, àwọn nǹkan olóòórùn dídùn ati òróró olówó iyebíye, ilé ìkó nǹkan ìjà ogun sí, ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra. Kò sí nǹkan tí ó wà ní ìpamọ́ ní ààfin Hesekaya ní ilé rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Inu Hesekiah si dùn si wọn, o si fi ile iṣura hàn wọn, fadaka, ati wura, ati nkan olõrun didùn, ati ikunra iyebiye, ati ile gbogbo ìhamọra rẹ̀, ati ohun gbogbo ti a ri ninu iṣura rẹ̀: kò si si nkankan ti Hesekiah kò fi hàn wọn ninu ile rẹ̀, tabi ni ijọba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekáyà gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀ tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìpanǹkan mọ́ hàn wọn—sílífà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Heṣekáyà kò fi hàn wọ́n.