Isaiah 39:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Aisaya tún bi í pé, “Kí ni wọ́n rí láàfin rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tó wà láàfin ni wọ́n rí. Kò sí ohun tí ó wà ní ilé ìṣúra mi tí n kò fihàn wọ́n.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn pe, Ohun gbogbo ti o wà ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkankan ti emi kò fi hàn wọn ninu iṣura mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?” “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi” ni ìdáhùn Heṣekáyà. “Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fi hàn wọ́n.”