Isaiah 39:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kó jọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkólọ sí Bábílónì. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni OLÚWA wí.