Isaiah 40:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi, ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n. Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀ èdè dàbí i ẹ̀kán-omi nínú garawa; a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n; ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.