Isaiah 40:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí, a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í. OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jérúsálẹ́mù kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbésè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ OLÚWA ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.