Isaiah 40:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé, àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀. Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa, ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On ni ẹniti o joko lori òbíri aiye, gbogbo awọn ti ngbe ibẹ si dabi ẹlẹngà; ẹniti o ta ọrun bi ohun tita, ti o si nà wọn bi àgọ lati gbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun jókòó lórí Ìtẹ́ ní òkè òbììrí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata. Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.