Isaiah 40:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n, wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀; nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n, tí wọ́n fi rọ bí ewéko, tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ, a kì yio gbìn wọn; nitõtọ, a kì yio sú wọn: nitõtọ igi wọn kì yio fi gbòngbo mulẹ: on o si fẹ́ lù wọn pẹlu, nwọn o si rọ, ãja yio si mu wọn lọ bi akekù koriko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n, kété tí a gbìn wọ́n, kété tí wọ́n tita ẹ̀kan nínú ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ, bẹ́ ni ìji-líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.