Isaiah 40:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀ nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú. Dájúdájú koríko ni eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí OLÚWA ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.