Isaiah 41:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin erékùṣù, kí àwọn eniyan gba agbára kún agbára wọn, kí wọ́n súnmọ́ ìtòsí, kí wọ́n sọ tẹnu wọn, ẹ jẹ́ kí á pàdé ní ilé ẹjọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
DAKẸ niwaju mi, Ẹnyin erekùṣu; si jẹ ki awọn enia tún agbara wọn ṣe: jẹ ki wọn sunmọ tosí; nigbana ni ki wọn sọ̀rọ: jẹ ki a jumọ sunmọ tosí fun idajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ dákẹ́ jẹ́ ẹ́ níwájúù mi ẹ̀yin erékùṣù! Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè tún agbára wọn ṣe! Jẹ́ kí wọn wá ṣíwájú kí wọn sọ̀rọ̀: Jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́.