Isaiah 41:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì, o kò ní rí wọn. Àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóo di òfo patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o wá wọn, iwọ kì yio si rí wọn, ani awọn ti o ba ọ jà: awọn ti o mba ọ jagun yio dabi asan, ati bi ohun ti kò si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀ta rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn. Gbogbo àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóò dàbí òfuuru gbádá.