Isaiah 41:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ, ìjì yóo sì fọ́n wọn ká. Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o fẹ́ wọn, ẹfũfu yio si fẹ́ wọn lọ, ãjà yio si tú wọn ká: iwọ o si yọ̀ ninu Oluwa, iwọ o si ṣogo ninu Ẹni-Mimọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì gbá wọn dànù Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú OLÚWA ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì.