Isaiah 41:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí àwọn talaka ati àwọn aláìní bá ń wá omi, tí omi kò sí, tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n, tí ọ̀nà ọ̀fun wọn gbẹ, èmi OLUWA yóo dá wọn lóhùn, èmi Ọlọrun Israẹli kò ní fi wọ́n sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati talakà ati alaini nwá omi, ti kò si si, ti ahọn wọn si gbẹ fun ongbẹ, emi Oluwa yio gbọ́ ti wọn, emi Ọlọrun Israeli ki yio kọ̀ wọn silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn talákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn ṣáàápá fún òrùngbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi OLÚWA yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.