Isaiah 41:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ta ló gbé ẹnìkan dìde ní ìhà ìlà oòrùn? Tí ó ń ṣẹgun ní ibikíbi tí ó bá fẹsẹ̀ tẹ̀? Ta ló fi àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ tí ó fi lè tẹ àwọn ọba mọ́lẹ̀? Idà rẹ̀ gé wọn bí eruku, ọfà rẹ̀ sì tú wọn ká bí àgékù koríko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o gbe olododo dide lati ìla-õrun wa, ti o pè e si ẹsẹ rẹ̀, ti o fi awọn orilẹ-ède fun u niwaju rẹ̀, ti o si fi ṣe akoso awọn ọba? o fi wọn fun idà rẹ̀ bi ekuru, ati bi akekù iyàngbo fun ọrun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ta ni ó ti ru ẹnìkan ṣókè láti ìlà-oòrùn wá, tí ó pè é ní òdodo sí iṣẹ́ tirẹ̀? Ó gbé àwọn orílẹ̀ èdè lé e lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájúu rẹ̀. Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀, láti kù ú níyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀.