Isaiah 41:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ mú wọn wá, kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa; kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa. Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò; kí á lè mọ àyọrísí wọn, tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú àwọn ère-òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún wa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́, kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọn kí àwa sì mọ àbájáde wọn níparí. Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá,