Isaiah 41:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti gbé ẹnìkan dìde láti ìhà àríwá, ó sì ti dé. Láti ìlà oòrùn ni yóo ti pe orúkọ mi; yóo máa gún àwọn ọba mọ́lẹ̀ bì ìgbà tí wọ́n gún nǹkan ninu odó, àní, bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń gún amọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti gbé ẹnikan dide lati ariwa, on o si wá: lati ilà-õrun ni yio ti ké pe orukọ mi: yio si wá sori awọn ọmọ-alade bi sori àmọ, ati bi alamọ̀ ti itẹ̀ erupẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ ẹnìkan láti ìlà oòrùn tí ó pe orúkọ mi. Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n, àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.