Isaiah 41:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí mo wo ààrin àwọn wọnyi, kò sí olùdámọ̀ràn kan, tí ó lè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ní ìbéèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori mo wò, kò si si ẹnikan; ani ninu wọn, kò si si olugbimọ̀ kan, nigbati mo bere lọwọ wọn, kò si ẹniti o le dahùn ọ̀rọ kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan— kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá, kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n.