Isaiah 41:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Agbẹ́gilére ń gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú ẹni tí ń fi òòlù lu irin ń kí ẹni tí ń dán irin tí wọ́n ti rọ, Ó ń wí pé: ‘Òjé tí a fi jó o dára.’ Wọ́n kàn án ní ìṣó, ó le dáradára, kò le mì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni gbẹnàgbẹnà ngbà alagbẹdẹ wura niyànju, ati ẹniti nfi ọmọ-owú dán a, ngbà ẹniti nlù ògún niyànju; wipe, o ṣetan fun mimọlù: o si fi iṣo kàn a mọra ki o má le ṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú, àti ẹni tí ó fi òòlù dán an mú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú. Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.” Ó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀.