Isaiah 42:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA; ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé. Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun; ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kọ orin titun sí OLÚWA ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú un wọn.