Isaiah 42:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè, ati àwọn abúlé agbègbè Kedari; kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀, kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki aginjù ati ilu-nla ibẹ gbé ohùn wọn soke, iletò wọnni ti Kedari ngbé: jẹ ki awọn ti ngbé apáta kọrin, jẹ ki wọn hó lati ori oke-nla wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí ihà àti àwọn ìlúu rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn ṣókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi kédárì ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ṣẹ́là kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.