Isaiah 42:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́, ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́? Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni, ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀; tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani fi Jakobu fun ikogun, ti o si fi Israeli fun ole? Oluwa ha kọ́ ẹniti a ti dẹṣẹ si? nitori nwọn kò fẹ rìn li ọ̀na rẹ̀, bẹ̃ni nwọn ko gbọ́ ti ofin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ó fi Jákọ́bù lélẹ̀ fún ìkógun, àti Ísírẹ́lì sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí? Kì í há ṣe OLÚWA ni, ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí? Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀; wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.