Isaiah 42:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ó jẹ́ kí wọ́n rí ibinu òun, ó sì fi agbára ogun rẹ̀ hàn wọ́n. Ó tanná ràn án lọ́tùn-ún lósì, sibẹ kò yé e; iná jó o, sibẹsibẹ kò fi ṣe àríkọ́gbọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni o ṣe dà irúnu ibinu rẹ̀ si i lori, ati agbara ogun: o si ti tẹ̀ iná bọ̀ ọ yika, ṣugbọn on kò mọ̀; o si jo o, ṣugbọn on kò kà a si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí, rògbòdìyàn ogun. Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀ èdè kò yé wọn; ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.