Isaiah 42:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ, tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀; ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀; tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n ṣóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú un wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú un rẹ̀: