Isaiah 43:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu, gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí, Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ. Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada; mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí OLÚWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bù ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ tèmi ni ìwọ ṣe.