Isaiah 43:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní, “N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín, n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè, ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa, olurapada nyin, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ̀ igbe-ayọ̀ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì; “Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónì láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, gbogbo ará Bábílónì nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.