Isaiah 43:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ, kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀. Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá; kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́, kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki gbogbo awọn orilẹ-ède ṣa ara wọn jọ pọ̀, ki awọn enia pejọ; tani ninu wọn ti o le sọ eyi, ti o si le fi ohun atijọ han ni? jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wọn jade, ki a le dá wọn lare; nwọn o si gbọ́, nwọn o si wipe, Õtọ ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo orílẹ̀ èdè kóra wọn jọ àwọn ènìyàn sì kóra wọn papọ̀. Ta ni nínú wọn tó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ yìí tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀? Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá láti fi hàn pé wọ́n tọ̀nà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”