Isaiah 44:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alagbẹdẹ rọ ãke kan, o ṣiṣẹ ninu ẹyín, o fi ọmọ-owú rọ ọ, o si fi agbara apá rẹ̀ ṣe e: ebi npa a pẹlu, agbara rẹ̀ si tan; ko mu omi, o si rẹ̀ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò, ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú; ó fi òòlù ya ère kan, ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀, Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un; kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.